Native Bible

Habakkuk 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?

Habakkuk 2:13 in English

Habakkuk 2:13 · Berean Standard Bible

Is it not indeed from the LORD of Hosts that the labor of the people only feeds the fire, and the nations weary themselves in vain?

Context

11Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn. 12“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú, tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó? 13Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán? 14Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa, bí omi ti bo Òkun. 15“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.