Habakuku 2:12
Habakkuk 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú, tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
Habakkuk 2:12 in English
Habakkuk 2:12 · Berean Standard Bible
Woe to him who builds a city with bloodshed and establishes a town by iniquity!
Context
10Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ. 11Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn. 12“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó? 13Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná
kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán? 14Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
bí omi ti bo Òkun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.