Habakuku 1:6
Habakkuk 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
Habakkuk 1:6 in English
Habakkuk 1:6 · Berean Standard Bible
For behold, I am raising up the Chaldeans *— that ruthless and impetuous nation which marches through the breadth of the earth to seize dwellings not their own.
Context
4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà. 5“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin. 6Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn. 7Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
yóò máa ti inú wọn jáde. 8Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.