Native Bible

Habakkuk 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, yóò máa ti inú wọn jáde.

Habakkuk 1:7 in English

Habakkuk 1:7 · Berean Standard Bible

They are dreaded and feared; from themselves they derive justice and sovereignty.

Context

5“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin. 6Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn. 7Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, yóò máa ti inú wọn jáde. 8Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun, 9gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú; wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.