Native Bible

Habakkuk 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.

Habakkuk 1:4 in English

Habakkuk 1:4 · Berean Standard Bible

Therefore the law is paralyzed, and justice never goes forth. For the wicked hem in the righteous, so that justice is perverted.

Context

2Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà? 3Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé? Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú. 4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà. 5“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin. 6Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.