Habakuku 1:3
Habakkuk 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé? Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
Habakkuk 1:3 in English
Habakkuk 1:3 · Berean Standard Bible
Why do You make me see iniquity? Why do You tolerate wrongdoing? Destruction and violence are before me. Strife is ongoing, and conflict abounds.
Context
1Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí. 2Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
Ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà? 3Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé?
Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú. 4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà. 5“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,
kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.