Gẹnẹsisi 6:9
Genesis 6:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ̀nyí ni ìtàn Noa. Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn.
Genesis 6:9 in English
Genesis 6:9 · Berean Standard Bible
This is the account of Noah. Noah was a righteous man, blameless in his generation; Noah walked with God.
Context
7Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” 8Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa. 9Wọ̀nyí ni ìtàn Noa.
Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. 10Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti. 11Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.