Native Bible

Genesis 49:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára.

Genesis 49:21 in English

Genesis 49:21 · Berean Standard Bible

Naphtali is a doe set free that bears beautiful fawns.*

Context

19“Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi, ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. 20“Oúnjẹ Aṣeri yóò dára; yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. 21“Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára. 22“Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso, àjàrà eléso ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. 23Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.