Gẹnẹsisi 49:13
Genesis 49:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni.
Genesis 49:13 in English
Genesis 49:13 · Berean Standard Bible
Zebulun shall dwell by the seashore and become a harbor for ships; his border shall extend to Sidon.
Context
11Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà,
àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.
Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì
àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà. 12Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,
eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ. 13“Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun,
yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,
agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni. 14“Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára
tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn. 15Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,
àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,
yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,
yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.