Native Bible

Genesis 49:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà, àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù. Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà.

Genesis 49:11 in English

Genesis 49:11 · Berean Standard Bible

He ties his donkey to the vine, his colt to the choicest branch. He washes his garments in wine, his robes in the blood of grapes.

Context

9Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda, o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi. Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún, ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde? 10Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un. 11Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà, àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù. Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà. 12Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ, eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ. 13“Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.