Native Bible

Genesis 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká.

Genesis 2:13 in English

Genesis 2:13 · Berean Standard Bible

The name of the second river is Gihon; it winds through the whole land of Cush.

Context

11Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá* àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. 14Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. 15Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.