Gẹnẹsisi 2:11
Genesis 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà.
Genesis 2:11 in English
Genesis 2:11 · Berean Standard Bible
The name of the first river is Pishon; it winds through the whole land of Havilah, where there is gold.
Context
9Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. 10Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá* àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.