Native Bible

Genesis 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.

Genesis 2:10 in English

Genesis 2:10 · Berean Standard Bible

Now a river flowed out of Eden to water the garden, and from there it branched into four headwaters:

Context

8Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. 9Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. 10Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá* àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.