Gẹnẹsisi 19:24
Genesis 19:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru* sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.
Genesis 19:24 in English
Genesis 19:24 · Berean Standard Bible
Then the LORD rained down sulfur and fire on Sodom and Gomorrah—from the LORD out of the heavens.
Context
22Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). 23Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. 24Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru* sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá. 25Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá ńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. 26Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.