Gẹnẹsisi 19:22
Genesis 19:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari).
Genesis 19:22 in English
Genesis 19:22 · Berean Standard Bible
Hurry! Run there quickly, for I cannot do anything until you reach it.” That is why the town was called Zoar.*
Context
20Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.” 21Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀. 22Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). 23Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. 24Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru* sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.