Gẹnẹsisi 19:25
Genesis 19:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá ńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.
Genesis 19:25 in English
Genesis 19:25 · Berean Standard Bible
Thus He destroyed these cities and the entire plain, including all the inhabitants of the cities and everything that grew on the ground.
Context
23Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. 24Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti sulfuru* sórí Sodomu àti Gomorra láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá. 25Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńlá ńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. 26Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀. 27Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.