Gẹnẹsisi 11:10
Genesis 11:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.
Genesis 11:10 in English
Genesis 11:10 · Berean Standard Bible
This is the account of Shem. Two years after the flood, when Shem was 100 years old, he became the father of Arphaxad.
Context
8Olúwa sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. 9Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli* nítorí ní ibẹ̀ ni Olúwa ti da èdè gbogbo ayé rú. Olúwa tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé. 10Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu.
Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi. 11Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. 12Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.