Native Bible

Galatians 4:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

Galatians 4:27 in English

Galatians 4:27 · Berean Standard Bible

For it is written: “Rejoice, O barren woman, who bears no children; break forth and cry aloud, you who have never travailed; because more are the children of the desolate woman than of her who has a husband.”*

Context

25Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.” 28Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. 29Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.