Galatia 4:25
Galatians 4:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.
Galatians 4:25 in English
Galatians 4:25 · Berean Standard Bible
Now Hagar stands for Mount Sinai in Arabia and corresponds to the present-day Jerusalem, because she is in slavery with her children.
Context
23Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara, ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí. 24Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari. 25Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27Nítorí a ti kọ ọ́ pé,
“Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn
tí kò bímọ,
bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,
ìwọ tí kò rọbí rí;
nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀
yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.