Galatia 4:28
Galatians 4:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki.
Galatians 4:28 in English
Galatians 4:28 · Berean Standard Bible
Now you,* brothers, like Isaac, are children of promise.
Context
26Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27Nítorí a ti kọ ọ́ pé,
“Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn
tí kò bímọ,
bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,
ìwọ tí kò rọbí rí;
nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀
yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.” 28Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. 29Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí. 30Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.