Native Bible

Ezra 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí.

Ezra 9:13 in English

Ezra 9:13 · Berean Standard Bible

After all that has come upon us because of our evil deeds and our great guilt (though You, our God, have punished us less than our iniquities deserve and have given us such a remnant as this),

Context

11èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì. 12Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’ 13“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí. 14Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là? 15Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.