Native Bible

Ezra 9:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.

Ezra 9:15 in English

Ezra 9:15 · Berean Standard Bible

O LORD, God of Israel, You are righteous! For we remain this day as a remnant. Here we are before You in our guilt, though because of it no one can stand before You.”

Context

13“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí. 14Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là? 15Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.