Native Bible

Ezra 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’

Ezra 9:12 in English

Ezra 9:12 · Berean Standard Bible

Now, therefore, do not give your daughters in marriage to their sons or take their daughters for your sons. Never seek their peace or prosperity, so that you may be strong and may eat the good things of the land, leaving it as an inheritance to your sons forever.’

Context

10“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Nítorí tí àwa kọ àṣẹ rẹ sílẹ̀ 11èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì. 12Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’ 13“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí. 14Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnikẹ́ni tí yóò là?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.