Native Bible

Ezra 9:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì.

Ezra 9:11 in English

Ezra 9:11 · Berean Standard Bible

that You gave through Your servants the prophets, saying: ‘The land that you are entering to possess is a land polluted by the impurity of its peoples and the abominations with which they have filled it from end to end.

Context

9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ ẹrú, Ọlọ́run wa kò fi wa sílẹ̀ nínú ìgbèkùn wa. Ó ti fi àánú hàn fún wa ni iwájú àwọn ọba Persia: Ó ti fún wa ní ìgbé ayé tuntun láti tún odi ilé Ọlọ́run wa mọ, kí a sì tún àwókù rẹ̀ ṣe, ó sì fi odi ààbò fún wa ní Juda àti ní Jerusalẹmu. 10“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, kí ni àwa yóò wí lẹ́yìn èyí? Nítorí tí àwa kọ àṣẹ rẹ sílẹ̀ 11èyí tí ìwọ ti pa fún wa láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé, ‘Ilẹ̀ náà ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti gbà n nì jẹ́ ilẹ̀ aláìmọ́ tó kún fún ẹ̀gbin àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, nípa ṣíṣe ohun ìríra àti híhu ìwà èérí ti kún ún láti ìkángun kan dé èkejì. 12Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbàkígbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì le máa jẹ ire ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le fi í sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayérayé.’ 13“Ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa jẹ́ àyọríṣí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, síbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù bí èyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.