Native Bible

Ezra 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda.

Ezra 1:8 in English

Ezra 1:8 · Berean Standard Bible

Cyrus king of Persia had them brought out by the hand of Mithredath the treasurer, who counted them out to Sheshbazzar the prince of Judah.*

Context

6Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún si gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá. 7Ní àfikún, ọba Kirusi mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé Olúwa jáde wá, tí Nebukadnessari ti kó lọ láti Jerusalẹmu tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀. 8Kirusi ọba Persia pàṣẹ fún Mitredati olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣeṣbassari ìjòyè Juda. 9Èyí ni iye wọn. Ọgbọ̀n àwo wúrà~~30 Ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà~~1,000 Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n~~29 10Ọgbọ̀n àdému wúrà~~30 Irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn~~410 Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn~~1,000

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.