Native Bible

Ezekiel 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ láti jogún ilé wọn. Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.

Ezekiel 7:24 in English

Ezekiel 7:24 · Berean Standard Bible

So I will bring the most wicked of nations to take possession of their houses. I will end the pride of the mighty, and their holy places will be profaned.

Context

22Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sì bà á jẹ́. 23“ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin! Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá. 24Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ láti jogún ilé wọn. Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́. 25Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán. 26Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì lórí ìdágìrì. Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.