Native Bible

Ezekiel 7:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sì bà á jẹ́.

Ezekiel 7:22 in English

Ezekiel 7:22 · Berean Standard Bible

I will turn My face away from them, and they will defile My treasured place. Violent men will enter it, and they will defile it.

Context

20Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn. 21Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́. 22Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sì bà á jẹ́. 23“ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin! Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá. 24Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ láti jogún ilé wọn. Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.