Esekiẹli 7:21
Ezekiel 7:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
Ezekiel 7:21 in English
Ezekiel 7:21 · Berean Standard Bible
And I will hand these things over as plunder to foreigners and loot to the wicked of the earth, who will defile them.
Context
19“ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó,
wúrà wọn yóò sì dàbí èérí
fàdákà àti wúrà wọn
kò ní le gbà wọ́n
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa.
Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn
tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ
nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn. 20Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà,
wọn sì ti fi ṣe òrìṣà,
wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀.
Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn. 21Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì
àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé,
wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́. 22Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn,
àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́;
àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀,
wọn yóò sì bà á jẹ́. 23“ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin!
Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.