Esekiẹli 7:26
Ezekiel 7:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì lórí ìdágìrì. Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.
Ezekiel 7:26 in English
Ezekiel 7:26 · Berean Standard Bible
Disaster upon disaster will come, and rumor after rumor. Then they will seek a vision from a prophet, but instruction from the priests will perish, as will counsel from the elders.
Context
24Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ
láti jogún ilé wọn.
Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára,
ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́. 25Nígbà tí ìpayà bá dé,
wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán. 26Wàhálà lórí wàhálà yóò dé,
ìdágìrì lórí ìdágìrì.
Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì,
ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà,
bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà. 27Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,
ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí,
ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì.
Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn,
èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn.
Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.