Esekiẹli 29:6
Ezekiel 29:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.
Ezekiel 29:6 in English
Ezekiel 29:6 · Berean Standard Bible
Then all the people of Egypt will know that I am the LORD. For you were only a staff of reeds to the house of Israel.
Context
4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. 5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ. 6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa.
“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n. 8“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.