Esekiẹli 29:4
Ezekiel 29:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Ezekiel 29:4 in English
Ezekiel 29:4 · Berean Standard Bible
But I will put hooks in your jaws and cause the fish of your streams to cling to your scales. I will haul you up out of your rivers, and all the fish of your streams will cling to your scales.
Context
2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ.
Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.” 4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. 5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ. 6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa.
“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.