Native Bible

Ezekiel 29:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

Ezekiel 29:5 in English

Ezekiel 29:5 · Berean Standard Bible

I will leave you in the desert, you and all the fish of your streams. You will fall on the open field and will not be taken away or gathered for burial. I have given you as food to the beasts of the earth and the birds of the air.

Context

3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ. Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.” 4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. 5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ. 6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.