Esekiẹli 29:8
Ezekiel 29:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.
Ezekiel 29:8 in English
Ezekiel 29:8 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the Lord GOD says: I will bring a sword against you and cut off from you man and beast.
Context
6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa.
“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n. 8“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.
“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,” 10nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.