Esekiẹli 29:9
Ezekiel 29:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa. “ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,”
Ezekiel 29:9 in English
Ezekiel 29:9 · Berean Standard Bible
The land of Egypt will become a desolate wasteland. Then they will know that I am the LORD. Because you said, ‘The Nile is mine; I made it,’
Context
7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n. 8“ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.
“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,” 10nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.