Esekiẹli 28:23
Ezekiel 28:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ, èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ, ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ, pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
Ezekiel 28:23 in English
Ezekiel 28:23 · Berean Standard Bible
I will send a plague against her and shed blood in her streets; the slain will fall within her, while the sword is against her on every side. Then they will know that I am the LORD.
Context
21“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ. 23Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa. 24“ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè. 25“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.