Esekiẹli 28:21
Ezekiel 28:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i,
Ezekiel 28:21 in English
Ezekiel 28:21 · Berean Standard Bible
“Son of man, set your face against Sidon and prophesy against her.
Context
19Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ” 20Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ. 23Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.