Esekiẹli 28:19
Ezekiel 28:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n, ní ẹnu ń yà sí ọ; ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”
Ezekiel 28:19 in English
Ezekiel 28:19 · Berean Standard Bible
All the nations who know you are appalled over you. You have come to a horrible end and will be no more.’”
Context
17Ọkàn rẹ gbéraga,
nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba. 18Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́. 19Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ” 20Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.