Esekiẹli 26:18
Ezekiel 26:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ; erékùṣù tí ó wà nínú Òkun ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’
Ezekiel 26:18 in English
Ezekiel 26:18 · Berean Standard Bible
Now the coastlands tremble on the day of your downfall; the islands in the sea are dismayed by your demise.”’
Context
16Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:
“ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí
ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!
Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo
òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;
ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ
lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀. 18Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì
ní ọjọ́ ìṣubú rẹ;
erékùṣù tí ó wà nínú Òkun
ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’ 19“Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.