Esekiẹli 26:20
Ezekiel 26:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
Ezekiel 26:20 in English
Ezekiel 26:20 · Berean Standard Bible
then I will bring you down with those who descend to the Pit, to the people of antiquity. I will make you dwell in the earth below like the ancient ruins, with those who descend to the Pit, so that you will no longer be inhabited or set in splendor * in the land of the living.
Context
18Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì
ní ọjọ́ ìṣubú rẹ;
erékùṣù tí ó wà nínú Òkun
ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’ 19“Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 21Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.