Esekiẹli 19:2
Ezekiel 19:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wí pé: “ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
Ezekiel 19:2 in English
Ezekiel 19:2 · Berean Standard Bible
and say: ‘What was your mother? A lioness among the lions! She lay down among the young lions; she reared her cubs.
Context
1“Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli 2wí pé:
“ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù?
Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. 3Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,
ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ. 4Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀,
wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn.
Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.