Native Bible

Ezekiel 19:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.

Ezekiel 19:3 in English

Ezekiel 19:3 · Berean Standard Bible

She brought up one of her cubs, and he became a young lion. After learning to tear his prey, he devoured men.

Context

1“Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli 2wí pé: “ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. 3Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ. 4Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn. Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. 5“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.