Esekiẹli 18:6
Ezekiel 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli, ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.
Ezekiel 18:6 in English
Ezekiel 18:6 · Berean Standard Bible
He does not eat at the mountain or look to the idols of the house of Israel. He does not defile his neighbor’s wife or approach a woman during her period.
Context
4Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápàá jẹ tèmi, ọkàn tó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. 5“Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà,
tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ 6tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga,
tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli,
ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀. 7Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀
gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un,
kò fi ipá jalè
ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò. 8Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá,
tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù.
Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀,
ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.