Esekiẹli 18:8
Ezekiel 18:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
Ezekiel 18:8 in English
Ezekiel 18:8 · Berean Standard Bible
He does not engage in usury or take excess interest, but he withholds his hand from iniquity and executes true justice between men.
Context
6tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga,
tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli,
ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀. 7Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀
gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un,
kò fi ipá jalè
ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò. 8Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá,
tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù.
Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀,
ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀. 9Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi,
tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo.
Ó jẹ́ olódodo,
yóò yè nítòótọ́,
ní Olúwa Olódùmarè wí. 10“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oníwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn, tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.