Esekiẹli 18:5
Ezekiel 18:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà, tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ
Ezekiel 18:5 in English
Ezekiel 18:5 · Berean Standard Bible
Now suppose a man is righteous and does what is just and right:
Context
3“Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, ẹ̀yin kí yóò pa òwe yìí mọ́ ni Israẹli. 4Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápàá jẹ tèmi, ọkàn tó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. 5“Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà,
tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ 6tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga,
tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli,
ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀. 7Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀
gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un,
kò fi ipá jalè
ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.