Native Bible

Ezekiel 18:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!

Ezekiel 18:17 in English

Ezekiel 18:17 · Berean Standard Bible

He withholds his hand from harming the poor * and takes no interest or usury. He keeps My ordinances and follows My statutes. Such a man will not die for his father’s iniquity. He will surely live.

Context

15“Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Israẹli, tí kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ 16tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò dá ohun ògo dúró tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò. 17Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! 18Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 19“Síbẹ̀, ẹ tún ń béèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò fi ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ́n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyèsi ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.