Esekiẹli 18:19
Ezekiel 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Síbẹ̀, ẹ tún ń béèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò fi ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ́n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyèsi ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.
Ezekiel 18:19 in English
Ezekiel 18:19 · Berean Standard Bible
Yet you may ask, ‘Why shouldn’t the son bear the iniquity of his father?’ Since the son has done what is just and right, carefully observing all My statutes, he will surely live.
Context
17Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,
kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù,
tí ó ń pa òfin mi mọ́,
tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi.
Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! 18Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 19“Síbẹ̀, ẹ tún ń béèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò fi ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ́n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyèsi ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè. 20Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburú náà la ó kà sí i lọ́rùn. 21“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àṣẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.