Esekiẹli 18:16
Ezekiel 18:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò dá ohun ògo dúró tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
Ezekiel 18:16 in English
Ezekiel 18:16 · Berean Standard Bible
He does not oppress another, or retain a pledge, or commit robbery. He gives his bread to the hungry and covers the naked with clothing.
Context
14“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ ọkùnrin, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe irú rẹ̀: 15“Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga
tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Israẹli,
tí kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ 16tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
tí kò dá ohun ògo dúró
tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè
ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ,
tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò. 17Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,
kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù,
tí ó ń pa òfin mi mọ́,
tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi.
Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! 18Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.