Esekiẹli 18:14
Ezekiel 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ ọkùnrin, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe irú rẹ̀:
Ezekiel 18:14 in English
Ezekiel 18:14 · Berean Standard Bible
Now suppose this son has a son who sees all the sins his father has committed, considers them, and does not do likewise:
Context
12Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára,
ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,
o gbójú sókè sí òrìṣà,
ó sì ń ṣe ohun ìríra. 13Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù.
Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀. 14“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ ọkùnrin, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe irú rẹ̀: 15“Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga
tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Israẹli,
tí kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ 16tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
tí kò dá ohun ògo dúró
tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè
ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ,
tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.