Native Bible

Ezekiel 11:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

Ezekiel 11:10 in English

Ezekiel 11:10 · Berean Standard Bible

You will fall by the sword, and I will judge you even to the borders of Israel. Then you will know that I am the LORD.

Context

8Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. 11Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. 12Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.