Native Bible

Ezekiel 11:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

Ezekiel 11:8 in English

Ezekiel 11:8 · Berean Standard Bible

You fear the sword, so I will bring the sword against you, declares the Lord GOD.

Context

6Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀. 7“Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀. 8Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí. 10Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.